Ìjọ Aposteli Kristi
Nàìjíríà Àti Òkè Òkun
ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
Akori Gbooro:
BÍBÉLÌ NÁÀ: ỌRỌ/ÌṢẸ ỌLỌ́RUN SI ÈNÌYÀN
Oṣù Kínní si oṣù Kejila 2026
Isọri III:
Àwọn Májẹ̀mú Ọlọ́run Àti Igbe Ayé Nínú Májẹ̀mú Láéláé
June 21, 2026
Ẹ̀KỌ́ 22
Akori:
Majẹmu Dafidi
Akọsórí:
Emi ti ba ayanfẹ mi da majẹmu, Emi ti bura fun Dafidi, ìránṣẹ́ Mi, iru ọmọ rẹ ni Emi o gbe kalẹ laelae, Emi o si maa gbe itẹ rẹ ro lati irandiran (Orin Dafidi 89:3,4).
Ọlọ́run ṣèlérí nipa itẹ Dafidi lati wa laelae, majẹmu titi aye fun irandiran, ogun-ini ti ìgbàgbọ́ ati ileri
ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Ninu Saamu yii, Onisaaamu yii n ronu nipa ìṣàkóso Ọlọ́run to ga julọ lori ohun gbogbo, o si n ran wa leti pe ko si ohun ti o N le ṣẹlẹ̀ laisi ìfẹ́ Rẹ̀. Bakan naa ni o tun n yọ si ileri Ọlọ́run fun Dafidi, ti o si sọ fun un pe iru ọmọ rẹ ni yoo maa jokoo lori itẹ naa nigba gbogbo. Nigba ti ileri yii bẹ̀rẹ̀ pẹlu ila Dafidi, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtumọ̀ rẹ jẹyọ níkẹyìn ninu ijọba Kristi, ti o wa lati inu idile Dafidi. Dafidi, Oluṣọ aguntan to nirẹlẹ, jẹ ẹni bi ọkan Ọlọ́run. O dari Israẹli pẹ̀lú iwa ododo ati òtítọ́ inu, ti n ṣafihan jíjẹ olootọ Ọlọ́run si majẹmu Rẹ.
Ileri yii si Dafidi n ran wa leti pe Bibeli ki iṣe akojọpọ awọn itan kan lasan-ọrọ/iṣe Ọlọ́run ni si wa. On ṣe afihan abuda aiyipada ti Ọlọrun fun wa, pẹlu iṣotitọ Rẹ ati awọn ìlérí ti On pamọ ni gbogbo irandiran. Nigba ti a ba n ro nipa eyi, a n gba wa niyanju lati ni ìgbẹ́kẹ̀lé ninu, awọn ileri Ọlọ́run ti n pa majẹmu mọ, Ẹni ti O ni eto rere fun ayé wa, gẹgẹ bi O ti ṣe fun Dafidi.
AṢARO LATI INU BÍBÉLÌ
Mon. 15: OLUWA Fi Ami Ororo Yan Dafidi (O. D. 89:19-21)
Tue. 16: OLUWA Fun Dafidi Ni Ìṣẹgun (O. D. 89:22-23)
Wed. 17; OLUWA Fi Oore-Ọfẹ Han Fun Un (O. D. 89: 24-25)
Thur. 18: Majẹmu OLUWA Duro Pẹlu Dafidi (O. D. 89:26-29).
Fri. 19: Majẹmu Naa Tan De Ori Awọn Ọmọ Rẹ (O. D. 89: 30-32).
Sat. 20: OLUWA Ko Ni Mu Iṣeun Ifẹ Rẹ Kuro (O. D. 89:33)
ÀṢÀRÒ FUN ÌFỌKÀNSÌN
1. Majẹmu Dafidi nṣafihan iṣeun ati iṣotitọ Ọlọ́run si awọn ti wọn și jẹ olootọ ati olufaraji si I.
2. Nigba ti a ba n gbe igbe aye títọ pẹlu ìṣẹ́ iriju ati awọn amuyẹ ìṣàkóso tòótọ́, Ọlọ́run jẹ́ olootọ lati ṣagbekalẹ májẹ̀mú Rẹ ati lati mu un ṣẹ pẹ̀lú wa.
ẸSẸ BIBELI FUN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: 1Kronika 17:11-14
ILEPA ATI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Lati sọ asoye nipa májẹ̀mú Ọlọ́run pẹlu Dafidi ti n ṣafihan Rẹ gẹgẹ bi Ọlọ́run majẹmu ati Olupa májẹ̀mú mọ.
ÀWỌN ERONGBA: Ni opin ẹ̀kọ́ yii, awọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ le:
i. ṣàlàyé ohun ti majẹmu Dafidi jẹ;
ii. ṣafihan Ọlọ́run gẹgẹ bi Ọlọ́run ti n pa májẹ̀mú mọ ti O si jẹ olootọ; ati
iii. tọkasi awọn ọna lati wọnu májẹ̀mú ibaṣepo titi aye pẹlu Ọlọ́run.
IFAARA
ORISUN Ẹ̀KỌ́: 2 SAMUELI 7:5-12; ORIN DAFIDI 89:3-4, 34-37; 132:11-12; ISE 2:22SWJ.
Ogo ni fun Ọlọ́run fun awọn ẹkọ ti O ti kọ wa ni awọn ọ̀sẹ̀ to ti kọjá lọ. Ni ọsẹ to kọjá yii, a wo: Ìjọba Israeli, nibi ti a ti kẹ́kọ̀ọ́ nipa iṣejọba awọn ọba Israeli ati agbekalẹ Ìjọba naa.
Ni ọsẹ yii, a o wo: Majẹmu Dafidi, eyi ti n ṣafihan jíjẹ olootọ Ọlọ́run si awọn ìlérí Rẹ lati irandiran. A o ri bi Ọlọ́run ti ṣèlérí fun Dafidi pe ìjọba rẹ yoo maa wa titi nípasẹ̀ arọmọdọmọ rẹ, a si fi ìdánilójú diduro tiiri ati itẹsiwaju rẹ mulẹ. Majẹmu Laelae yii n tọkasi iṣotitọ ati ifaraji Ọlọ́run ti ki i yẹ si mimu awọn ileri Rẹ ṣẹ fun awọn ti wọn ba ṣi jẹ olootọ si I laiyẹsẹ.
Bi oni ti jẹ ọjọ awọn Baba ti ọdun 2026, a n ran wa leti nipa bi Ọlọ́run, Baba wa ọ̀run, ti jẹ olootọ nigba gbogbo ni titọju wa. Ẹ jẹ ki a kọ lati gbe ibaṣepọ to le koko pẹ̀lú Rẹ ro, ẹni ti yoo ba fi ogun ini titi lae silẹ fun awọn iran ọjọ ọla. A o bukun fun wa ni orúkọ Jesu. Amin.
KOKO EKO
I. MAJẸMU AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN PẸLU DÁFÍDÌ
II. IṢOTITỌ ỌLỌ́RUN SI MAJẸMU DÁFÍDÌ
ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
I. MAJẸMU AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN PẸ̀LÚ DAFIDI (2 Sam. 7:5-12; O. D. 89:3,4).
Nigba ti ọjọ rẹ ba pe, ti ìwọ o si sun pẹ̀lú awọn baba rẹ, Emi o si gbe iru ọmọ rẹ leke lẹ́yìn rẹ, eyi ti o ti inu rẹ jade wa, Emi o si fi idi ìjọba rẹ kalẹ (2 Sam. 7:12).
a. Ọlọ́run, ninu titobi ọlanla Rẹ jẹ Oluṣagbekalẹ májẹ̀mú ati Olùpa majẹmu mọ. Pẹlu pe O jẹ Aiku, O finnufindọ wọnu idipọ/àdéhùn pẹlu eniyan ti i ṣe ẹni kiku ati alaipe.
b. Ni Heberu, "beriyth" n tọkasi àdéhùn laarin ẹgbẹ́(ẹni) meji, nibi ti ẹgbẹ́ (ẹni) kọọkan ti ni lati faraji si pipa awọn ìlérí ti wọn ṣe mọ.
d. Òye niti majẹmu pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ aarin gbungbun ninu Bibeli, o sin ṣafihan abuda ara ọtọ Rẹ. A gbọ́dọ̀ ni ilepa lati maa ṣafarawe abuda Ọlọ́run yii ninu aye ti wa naa
e. 2 Sam. 7:5-17: Ọlọ́run dá majẹmu ti ko ni tori ninu pẹlu Dafidi, yàtọ̀ si majẹmu Rẹ pẹlu Noa, Abrahamu ati Israẹli.
ẹ. O. D 89:3-4: Ọlọ́run ṣèlérí lati ṣagbekalẹ iru ọmọ Dafidi O si gbe itẹ rẹ ro titi laelae (1 Kron. 22:9-10; 28:5-6). Iru Ọlọ́run olotitọ wo ni a n sin yii!
f. Lati ni iriri majẹmu Ọlọ́run nitootọ, a gbọ́dọ̀ mu ibaṣepọ timọtimọ pẹlu Rẹ ni pataki julọ, ki a gbe ibaṣepọ titi aye ro pẹlu Rẹ ki awọn ileri Rẹ le wa si ìmúṣẹ ninu aye wa. Ìṣẹ́ isin wa tootọ si Ọlọ́run yoo fi ipa rere lélẹ̀ eyi ti yoo maa fọhun síbẹ̀ lẹyin ti a ba lọ tan.
II. IṢOTITỌ ỌLỌ́RUN SI MAJẸMU DAFIDI (O. D. 89: 34-37; 132:11-12; Işe 2:22swj).
Nitori ti iṣe wolii, ati bi o ti mọ pe, Ọlọ́run ti fi ibura ṣe ileri fun un pe, Ninu iru ọmọ inu rẹ, oun o mu ọkan ìjókòó lori itẹ rẹ (Iṣe. 2:30)
a. O. D. 89:34: Ọlọ́run, Oludamajẹmu ati Olupa majẹmu mọ jẹ olootọ si awọn ileri Rẹ nigba gbogbo (Ìṣe 2:29-37). Eyi mu ki Bibeli ṣe e sinmile ti o si wa titi laelae.
b. Ila 34-37; Ọlọ́run n kiyesi awọn majẹmu Rẹ lati ri i daju pe a ṣe ìmúṣẹ wọn ni pipe. Àwọn ileri Rẹ jẹ ojulowo síbẹ̀, niwọn igba ti a ba ti jẹ olootọ si ojúṣe ti wa, bi o tilẹ̀ jẹ́ pe eniyan le kuna (132:11, 12).
d. 132:11-12: O bu ọla fun májẹ̀mú Rẹ pẹlu Dafidi nipa ṣiṣe agbekalẹ ila ìdílé reẹ gẹgẹ bi oluṣejọba Israeli ti o to fun gbogbo iran.
e. Ila 11: Ileri lati mu ila ìdílé Dafidi gẹgẹ bi ọba duro, níkẹyìn n tọkasi ìmúṣẹ ọjọ ọla ti ìṣejọba Mesaya, ti a muṣẹ ninu Kristi Jesu, Ọba awọn ọba (Ifi. 22:5).
ẹ. Ìṣe 2:22swj: Pétérù ṣàlàyé bi ajinde Jesu ti mu asọtẹlẹ Dafidi ṣẹ, pe, agọ̀ ara Mèsáyà ki yoo dibajẹ, eyi n ṣafihan isopọ laarin Dafidi ati Jesu (O. D 16:10).
f. Majẹmu Dafidi n ṣafihan ipa ara ọtọ Dafidi ninu itan Bibeli ati itẹsiwaju laarin Majẹmu Laelae ati Majẹmu Tuntun, ti o yọrisi ọdọ Jesu, Iru ọmọ Dafidi ti a ti ṣèlérí naa (Lk. 1:32).
AWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RI KỌ
1. Majẹmu Dafidi n ru awọn onigbagbọ sókè lati maa bọlá fun Ọlọ́run ki wọn si maa gbe ogun ini titi laelae ro.
2. Iṣotitọ Ọlọ́run n fun wa ni ẹmi irẹlẹ, o n ru wa sókè lati mọ títóbi julọ ìjọba Rẹ ati lati dagba nipa tẹmi.
ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1. Ṣalaye iṣotitọ Ọlọ́run ati títóbi julọ Rẹ ninu majẹmu Dafidi. Awọn ẹkọ wo ni a le kọ lara eyi lonii?
2. Bawo ni awọn onigbagbọ ninu Kristi ṣe le mu majẹmu Ọlọ́run dúró lode lonii?
ÌDÁHÙN TI A DABAA FUN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ 1
* Ọlọ́run ninu titobi julọ Rẹ, yan Dafidi gẹ́gẹ́ bi ẹni ami ororo Rẹ O si da majẹmu àìnípẹ̀kun lati fidi ìjọba rẹ múlẹ̀.
* Majẹmu yii ṣan wọnu majẹmu ti Mèsáyà pẹlu awọn ènìyàn Ọlọ́run.
* Dafidi ò gba majẹmu yii nípasẹ̀ iwa òdodo rẹ; ìyàn Ọlọ́run, ti o da lori oore-ọfẹ Rẹ ni, kii ṣe mímọ-ọn-ṣe Dafidi.
* Ninu iṣotitọ Rẹ, Ọlọ́run ri i dájú pé majẹmu yii di mimúṣẹ (O. D. 89:34).
* Dafidi ko ipa pataki nipa gbigbe ibaṣepọ timọtimọ pẹlu Ọlọ́run ro, ní bí o ti ṣàkóso pẹlu òtítọ́ inu, ọkan olùsọ-àgùntàn, ati iwa irẹlẹ to jinlẹ.
* Awon eko fun wa lonii:
* Awọn obi gbọ́dọ̀ ko/gbe ogun ini oniwa-bi-Ọlọrun ro fun awọn ọmọ wọn.
* Eyi n yanana pàtàkì ogun ini ìdílé ati ipa rẹ lori awọn iran ọjọ́ ọla.
IDAHUN SI IBEERE 2
A le pa majẹmu Ọlọ́run mọ laaye ninu aye wa lonii nipa:
i. Gbígbé ibaṣepọ to kun fun Ẹ̀mi ti o si le koko ro pẹlu Ọlọ́run;
ii. Ṣiṣe agbekalẹ akoko ìfọkànsìn ti ìdílé lojoojumọ;
iii. Kíkọ ìdílé rẹ ni awọn ẹkọ ati ilana Bibeli to ṣe iyebiye;
iv. Fifaaye gba Jesu lati dari ati lati maa tọ idile rẹ;
v. Fifi Jésù han ìdílé/ẹbi rẹ - Oun ni ẹ̀bùn ti o tobi julọ;
vi. Fifun Ọlọ́run ni ìjọsìn tòótọ́ ati eyi to ṣe itẹwọgba;
vii. Jijẹ ẹni to n kopa to si n ṣe deede ninu ìṣẹ́ isin Ọlọ́run pẹ̀lú awọn ọmọ rẹ;
viii. Ṣiṣatilẹyin ìṣe Ọlọ́run ninu ijọ ti o n lọ; ati
ix. Riri isẹra ẹni/ibawi gẹ́gẹ́ bi ami ifẹ Ọlọ́run ati ipongbẹ Rẹ lati ṣe odiwọn wa sinu àwòrán Rẹ.
ÀMÚLÒ FUN IGBE AYE ẸNI
Ọlọ́run ni eto ara-ọ̀tọ̀ fun olukuluku wa, gẹgẹ bi O ti ni in fun eyi si bẹ̀rẹ̀ pẹlu gbígbẹkẹle E ati titẹle awọn àṣẹ Rẹ. A le ma fi igba gbogbo ni ẹkunrẹrẹ oye eto Rẹ, ṣugbọn a le ni ìdánilójú pe ọna Rẹ tayọ ohunkohun ti a le finuro. Ẹ jẹ ki a kọjú wasi gbigbe igbe aye to n bu ọlá fun Ọlọ́run ki a si kó ogun ini ti n ṣafihan ìfẹ́ ati iṣotitọ Rẹ. Gẹgẹ bi baba to mọ ikẹ ati igẹ ti maa n tọju awọn ọmọ rẹ, Ọlọ́run wa fun wa nigba gbogbo, On tọ wa pẹlu itọju ìfẹ́ Rẹ̀. Ẹ jẹ ki a maa gbe ayé wa ni ọna to ba ifẹ Rẹ mu, ki a gbẹkẹle E lati dari wa si ọjọ́ ọ̀la ti O ti ṣètò fun wa.
IGUNLẸ
Eyi ni igunlẹ Ẹ̀kọ 22. A gba wa níyànjú lati faramọ majẹmu Ọlọ́run, ati gẹgẹ bi obi, oluṣo-aguntan ati olutọnisọna, a gbọ́dọ̀ lakaka lati gbe ogun ini oníwà-bí-Ọlọ́run ti yoo wa laelae ró, gẹgẹ bi ti majẹmu Dafidi. Awọn obi gbọ́dọ̀ maa gbadura fun ọjọ́ ọ̀la awọn ọmọ wọn, ki wọn maa ṣàfẹ́rí ìtọ́ni ati ìbùkún Ọlọ́run fun wọn.
ÀkíyèsíÌjọ Aposteli Kristi

Àkíyèsí